Matthew 8:14-17

Jesu wo ọ̀pọ̀ aláìsàn sàn

14 aNígbà tí Jesu sì dé ilé Peteru, ìyá ìyàwó Peteru dùbúlẹ̀ àìsàn ibà. 15Ṣùgbọ́n nígbà tí Jesu fi ọwọ́ kan ọwọ́ rẹ̀, ibà náà fi í sílẹ̀, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ó sì dìde ó ń ṣe ìránṣẹ́ fún wọn.

16Nígbà tí ó di àṣálẹ́, ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó ní ẹ̀mí èṣù ni a mú wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ lé àwọn ẹ̀mí èṣù náà jáde. A sì mú gbogbo àwọn ọlọ́kùnrùn láradá. 17 bKí èyí tí a ti sọ láti ẹnu wòlíì Isaiah lè ṣẹ pé:

“Òun tìkára rẹ̀ gbà àìlera wa,
ó sì ń ru ààrùn wa.”
Copyright information for YorBMYO